ÀDÚRÀ AFỌṢẸ
₦300.00
ọmọ obinrin opó Sarefati, kò ni kú lojú Elijah, ọmọkunrin ará Ṣunemu kò ni kú lojú Eliṣa, ọmọ rẹ kò ni kú…
Ilẹ̀ Goṣeni ni wọn ti ń ṣe iṣẹ́ fun irinwo ọdún ti kò ni èrè, bi a ba de ilẹ Kenaani ni ọmọ Abrahamu yóò ko èrè nibiti wọn ko ṣiṣẹ, èrè ni t’emi ninu ọdún yi…
Ikuna ni Saulu ba pade lọdọ abokúsọrọ, gbogbo ọ̀na ti ọtá rẹ ba ń gba lati ṣe ọ ni ibi, ikuna ni yóò pade…
Bi Saulu ba ṣe aṣeti bi ti Dafidi kọ, awopọọkọ kò ni gba orí Johanu ki o tun gba ti Jesu, o ṣèèwọ̀, orí rẹ kò ni gbabọde
kẹtẹkẹtẹ ti sun kan ogiri, o ti fọhùn bi ènìyàn, bi o ba wu Balaamu ki o gbọ, aigbọ Balaamu ẹsin lo máa ṣe nitorí ẹniti o gbẹ́kẹ̀lé kẹkẹ ti o gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin ti o fẹ ba Israẹli ja, ẹṣin lọ, ọ̀tá rẹ yóò ṣe ẹsin lọdún yi.
Reviews
There are no reviews yet.