Sale!

ILÉ ÀDÚRÀ LA Ó MÁA PE ILÉ MI

300.00

Ade ori kiniun ẹranko kan kò gbọdọ ṣi, bata ẹsẹ ajanaku kò ni wọ ọmọ ẹranko miran ni ẹsẹ, ipo mi ninu ayé ma jẹ ki o di ti ẹlomiran. Oluwa ti fi mi ṣe ori, n ó ni jẹ iru mọ, eewọ ni, ẹyin ọ̀tá mi, ibi ti a ba ti fi ṣe ori, a kò gbọdọ fi ibẹ tẹ ilẹ̀, ori ni mi, n ó ni di iru…

Ko si ẹniti mo le tọ lọ fun igbega a fi iwọ Ọlọrun, oloogun ti sa oogun tirẹ̀ ẹlẹbọ ti gbé ẹbọ tirẹ̀, onigbadi ti lo igbadi tirẹ̀, gbogbo awọn nkan wọnyi okú ọlọrun ni niwaju iwọ Ọlọrun Israẹli, iwọ lo ni gbogbo agbara laye ati lọrun, Oluwa wa gbe mi ga ninu ọdún yi….

Mose ti bori Farao bi ọyẹ ti n bori oruru, Dafidi ti bori Goliati bi ojo gidigidi ti bori ọgbẹlẹ, okun ti pinya ki ọmọ Israẹli ki o kọja, ki omi ki o gbe Farao lọ, ki agbára ọtá ki o di okú, ki imọ ọtá ki o di okú ninu aye mi…

Okun pupa kò ni ri ọmọ Israẹli ki o máa pinya, o jẹ dandan, ki Jordani pada sẹhin lẹhin ọmọ Israẹli gbogbo ogun idile ni iwaju mi ki o máa pinya gbogbo ogun idile ni ẹyin ki o máa ṣubu, a bi ẹ kò mọ wipe Israẹli kò gbe si ilẹ̀ Egipti, abẹrẹ kì í gbe si aṣọ, bẹẹ ni emi náà kò gbudọ gbe sinu iṣẹ́, o jẹ didan n ó ṣe aṣeyọri…

Categories: , ,

Reviews

There are no reviews yet.

Be the first to review “ILÉ ÀDÚRÀ LA Ó MÁA PE ILÉ MI”

Your email address will not be published. Required fields are marked *